Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ̀ máa bá a - jẹ kí amọn pé: ẹnikẹni ti Ọlọhun bá fun ni ọmọbirin meji tabi arabinrin meji, ti o wa mojuto itọju wọn daada pẹlu ẹkọ ati titọwọn sọna lọ sibi iṣẹ rere, ti o sì ṣọwọn lára kuro nibi aburu ati bẹẹ bẹẹ lọ titi ti wọ́n fi dagba, irufẹ ẹnibẹẹ yóò wà pẹlu Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - ní ọjọ igbende gẹgẹ bi ika ọwọ méjèjì yii, Anọbi ṣe àpèjúwe rẹ̀ pẹlu ika ilabẹ ati ika mogajuwọnlọ tí ó pa wọ́n pọ̀ mọ́nrawọn.