Wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ? O sọ pe: Irun ọran-anyan kiki ni asiko rẹ ti Ọba aṣofin pa aala rẹ, Lẹyin naa, ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji, pẹlu ṣíṣe daadaa si awọn mejeeji, ati mimojuto ẹtọ awọn mejeeji, ati gbigbe ṣiṣẹ awọn mejeeji ju silẹ, Lẹyin naa, jija ogun si oju ọna Ọlọhun, fun gbigbe ọrọ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- soke, ati dida aabo bo ẹsin Isilaamu ati awọn Musulumi, ati fifi awọn ami rẹ han, ìyẹn pẹlu ẹmi ati owo. Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: O sọ awọn iṣẹ yii fun mi; ti mo ba sọ fun un pe: Lẹyin naa èwo? Dajudaju o maa ṣe alekun rẹ fun mi.