Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí o ba ki irun alufajari ti wa ninu iṣọ Ọlọhun ati ààbò Rẹ, yoo maa da aabo bo o, yoo si maa ṣẹ́gun fun un. Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣọ wa lara kúrò nibi títú àdéhùn naa ati biba a jẹ́, yálà pẹlu gbigbe irun alufajari ju silẹ ni, tabi ìkọlù ẹni ti n ki i, ẹni tí ó bá ṣe iyẹn ti ba ààbò yii jẹ́, o si ni ẹtọ si àdéhùn ìjìyà ti o le koko pẹ̀lú pe ki Ọlọhun bi i leere nípa ohun tí o ṣe àṣeètó nibẹ nibi ẹtọ Rẹ, ẹni tí Ọlọhun ba bi léèrè, yoo gba ẹsan lara rẹ, lẹ́yìn náà yoo da oju rẹ bo ilẹ̀ ninu iná.