Lati ọdọ 'Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Ko si ninu ọmọniyan to jẹ musulumi ti irun ọran-anyan kan wa ba a, ti o wa ṣe aluwala rẹ daadaa ati ipaya rẹ ati rukuu rẹ, afi ki o jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ, niwọn igba ti ko ba mu ẹṣẹ nla wa, gbogbo igba si ni ìyẹn maa ri bẹ́ẹ̀". O ni alaafia - Muslim gba a wa
explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ko si ninu musulumi kan ti asiko irun ọran-anyan maa wọle ba a ti o si ṣe aluwala rẹ daadaa ti o si pe e, lẹyin naa o n paya nibi irun rẹ pẹlu pe ọkan rẹ ati awọn orikee rẹ gbogbo rẹ dojukọ Ọlọhun ti wọn n ranti titobi Rẹ lori irun, O si pe awọn iṣẹ irun gẹgẹ bii rukuu ati iforikanlẹ ati eyi ti o yàtọ̀ si i, afi ki irun yii jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ kekere, niwọn igba ti ko ba ti da ẹṣẹ nla kan ninu awọn ti o tobi ninu awọn ẹṣẹ, ati pe ọla yii ma maa lọ bẹẹ pẹlu lilọ igba ati nibi gbogbo irun.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Irun jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun awọn ẹṣẹ, oun ni eyi ti ẹru ba ṣe aluwala rẹ daadaa, ti o si ki i ni olupaya ti o fi wa oju rere Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
  • Ọla ti o n bẹ fun idunnimọ awọn ijọsin, ati pe o jẹ okunfa fun aforijin awọn ti wọn kere ninu awọn ẹṣẹ.
  • Ọla ti o n bẹ fun ṣíṣe aluwala daadaa, ati kiki irun daadaa ati nini ipaya nibẹ.
  • Pataki jijina si awọn ti o tobi ninu awọn ẹṣẹ lati ṣe aforijin àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké.
  • Awọn ẹṣẹ ńláńlá ko ṣee parẹ afi pẹlu ironupiwada.