Saabe Jareer ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe oun dunnimọ oun si ṣadehun fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo ati pipe awọn irun maraarun-un ti wọn jẹ ọran-anyan ni ọsan ati alẹ, pẹlu awọn majẹmu rẹ ati awọn origun rẹ ati awọn dandan rẹ ati awọn sunnah rẹ, ati lori pipe saka ti a ṣe ni ọran-anyan, oun ni ijọsin ti owo ti o jẹ dandan, ti wọn maa n gba lọwọ awọn ọlọrọ ti wọn si maa n fun awọn ti wọn lẹtọọ si i ninu awọn alaini ati awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn, ati lori itẹle fun awọn adari, ati iṣiti fun gbogbo Musulumi, ìyẹn pẹlu ṣíṣe ojúkòkòrò láti ṣe e ni anfaani, ati mimu daadaa de ọdọ rẹ, ati titi aburu danu fun un pẹlu ọrọ ati iṣẹ.