explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba ki awọn irun ọran-anyan maraarun-un ti ko le nnkankan kun ninu awọn nafila, ti o si gba awẹ Ramadan ti ko gba awọn aṣegbọrẹ, ti o ni adisọkan jijẹ ẹtọ nnkan ẹtọ ti o si ṣe é, ti o ni adisọkan jijẹ eewọ nnkan eewọ ti o si jina si i, dajudaju yoo wọ alujanna.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ojúkòkòrò Musulumi lori ṣíṣe awọn ọran-anyan ati gbigbe awọn eewọ ju silẹ, ati pe ki afojusun rẹ jẹ wiwọ alujanna.
  • Ṣíṣe pataki ṣíṣe nnkan ẹtọ ati ini adisọkan jijẹ ẹtọ rẹ, ati ṣíṣe nnkan eewọ ni eewọ ati ini adisọkan jijẹ eewọ rẹ.
  • Ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn nnkan eewọ ju silẹ jẹ okunfa fun wiwọ inu alujanna.