Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju o gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: "Ẹ sọ fun mi ti akeremọdo kan ba wa ni ẹnu ọ̀nà ẹni kọọkan ninu yin ti o n wẹ nibẹ ni ojoojumọ lẹẹmarun-un, njẹ ìyẹn le ṣẹ nǹkan kan kù nínú ìdọ̀tí rẹ bi?" wọn sọ pe: Ko lee ṣẹ nnkan kan ku ninu ìdọ̀tí rẹ, o sọ pe: "Gẹgẹ bẹẹ ni iru awọn irun maraarun-un, Ọlọhun maa n pa awọn àṣìṣe rẹ pẹlu rẹ". O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
explain-icon

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi àwọn irun maraarun-un lojoojumọ nibi imukuro rẹ ati pipa awọn ẹṣẹ kéékèèké rẹ ati awọn àṣìṣe, o fi we akeremọdo kan ti o wa ni ẹnu ọ̀nà ọmọniyan ti o n wẹ ninu rẹ lojoojumọ ni ẹẹmaraun-un, ti ko nii ṣẹ nnkan kan ku ninu ìdọ̀tí rẹ ati ẹgbin rẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọla yii jẹ ẹṣa fun pipa awọn ẹṣẹ kéékèèké rẹ, sugbọn awọn ẹṣẹ nla, ironupiwada jẹ dandan nibẹ.
  • Ọla ti o n bẹ fun kiki irun maraarun-un ati sisọ wọn pẹlu awọn majẹmu wọn ati awọn origun wọn ati awọn dandan wọn ati awọn sunnah wọn.