Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: «Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro, ati pe mo ti wa gbero lati paṣẹ ki wọn o gbe irun duro, lẹyin naa ki n wa pa ẹnikan laṣẹ ki o ki i, lẹyin naa ki n wa gbera pẹlu awọn ọkunrin kan ti idi igi wa pẹlu wọn lọ si ọdọ awọn ijọ kan ti wọn o ki n wa ki irun ni masalaasi, ki n si sun ile wọn mọ wọn lori». O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
explain-icon

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ nipa awọn munaafiki ati kikọlẹ wọn nibi wiwa ki irun, agaga julọ irun Ishai ati Asunbaa, ati pe dajudaju ti wọn ba mọ odiwọn ẹsan ati laada ti o wa nibi wiwa ki mejeeji pẹlu janmọọn ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ rirakoro gẹgẹ bi ọmọde ṣe maa n rakoro pẹlu ọwọ ati orunkun. Ati pe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ti pinnu lati paṣẹ pe ki wọn o gbe irun duro, ki o wa fi ọkunrin kan si aaye rẹ lati ṣiwaju awọn eeyan, lẹyin naa ki o wa gbera ti awọn ti wọn gbe idi igi lọwọ si wa pẹlu rẹ, lati lọ ba awọn ọkunrin ti wọn o ki n ki irun janmọọn ninu masalaasi, lẹyin naa ki o wa da’na sun ile wọn; latari ini-agbara ẹṣẹ ti wọn ko si nibi iyẹn, - ṣugbọn ko ṣe e – latari awọn ti wọn wa ninu ile bii awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn o mọ nkankan ati awọn to yatọ si wọn ninu awọn ti wọn ni idiwọ (ti wọn ni awijare), awọn ti ko si ẹṣẹ kankan fun wọn.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Aburu imaa fa sẹyin nibi kiki irun janmọọn ninu masalaasi.
  • Awọn munaafiki o gbero pẹlu irun wọn ayaafi ṣekarini ati ṣekagbọni, nitori naa wọn ko nii wa ki irun ayaafi ni igba ti awọn eeyan maa ri wọn.
  • Titobi ẹsan ti n bẹ nibi kiki irun Ishai ati Asunbaa pẹlu janmọọn, ati pe awọn mejeeji lẹtọọ si imaa wa ki wọn koda ko jẹ pẹlu rirakoro.
  • Imaa ṣọ irun Ishai ati irun Asunbaa, lila lo jẹ kuro nibi jíjẹ́ munaafiki, ati pe imaa fa sẹyin nibi mejeeji ninu iroyin awọn munaafiki lo wa.