Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe khutubah ni ọjọ 'Arafah, ni hajj idagbere, ni ọdun kẹwàá ninu hijira, wọn sọ ọ ni orúkọ yẹn; nitori pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dagbere fun awọn eniyan nibẹ, O pa awọn eniyan patapata láṣẹ lati bẹru Oluwa wọn pẹlu mimu awọn àṣẹ Rẹ ṣẹ ati jijina si awọn ẹ̀kọ̀ Rẹ. Pe ki wọn maa ki awọn irun maraarun-un ti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ṣe wọn ni ọran-anyan ni ọsan ati alẹ. Pe ki wọn maa gba awẹ oṣu Ramadan. Pe ki wọn maa yọ saka awọn dukia fun awọn ti wọn lẹtọọ si i ki wọn si ma ṣe ahun pẹlu rẹ. Pe ki wọn maa tẹle awọn ti Ọlọhun fi ṣe adari le wọn lori, yàtọ̀ si ibi ṣiṣẹ Ọlọhun, Ẹni ti o ba ṣe awọn nnkan ti a dárúkọ yìí, ẹsan rẹ ni wiwọ alujanna.