explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo dáadáa ati àǹfààní fun ẹlòmíràn, bóyá ọrọ ni tabi iṣẹ, o maa jẹ sàárà, ẹ̀san si n bẹ nibẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Sàárà kò mọ lori nǹkan ti èèyàn n yọ jáde ninu dúkìá, bi ko ṣe pe o ko gbogbo oore ti ọmọniyan n ṣe tàbí sọ sínú, ti o si maa de ọdọ ẹlòmíràn.
  • O n bẹ nibẹ isẹnilojukokoro lati maa ṣe dáadáa ati gbogbo nǹkan ti àǹfààní ba n bẹ nibẹ fun ẹlòmíràn.
  • Ki èèyàn ma fi ojú kere dáadáa kankan, kódà ki o kéré.