Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi nkan mẹẹrin, lẹyin ataaya igbẹyin ati siwaju salamọ ninu irun, o si tun pa wa laṣẹ ki a maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibẹ, Ikinni: Nibi iya saare. Ẹẹkeji: Nibi iya ina ati pe ìyẹn ni ọjọ igbedide. Ẹẹkẹta: Nibi fitina iṣẹmi bi awọn adun aye ti o jẹ eewọ ati awọn iruju ti maa n sọni nu, ati nibi fitina iku, ìyẹn ni àsìkò pipọka iku, bii yiyẹ kuro ninu Isilaamu tabi Sunnah, tabi fitina saare gẹgẹ bii ibeere awọn malaika mejeeji. Ẹẹkẹrin: Fitina al-Masiihu ad-Dajjāl eleyii ti yio jade ni igbẹyin aye, Ọlọhun yio fi i dan awọn ẹru Rẹ wo; o wa darukọ rẹ lọ́tọ̀ latari titobi fitina rẹ ati isọninu rẹ.