explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn olori kan maa jẹ lé wa lori, a maa mọ awọn kan ninu awọn iṣẹ wọn; nitori pe wọn ba nnkan ti wọn mọ ninu Sharia mu, a si maa tako awọn kan ninu wọn; nitori wọn yapa ìyẹn, Ẹni ti o ba korira ibajẹ pẹlu ọkan rẹ, ti ko kapa lori atako; o ti bọ kuro ninu ẹṣẹ ati ṣọbẹ-selu, Ẹni ti o ba kapa lori atako pẹlu ọwọ tabi ahọn, ti o wa tako ìyẹn fun wọn o ti la kuro nibi ẹṣẹ ati kikopa nibẹ, Ṣugbọn ẹni ti o ba yọnu si iṣe wọn ti o si tẹle wọn lori rẹ, o maa parun gẹgẹ bi wọn ṣe parun. Lẹyin naa wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pe: Njẹ a ko nii ba awọn adari ti wọn ṣe pe eyi ni iroyin wọn ja? O wa kọ fun wọn kuro nibẹ, o wa sọ pe: Rara, lópin ìgbà tí wọ́n ba ṣi n gbé ìrun duro láàárín yin.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ninu awọn itọka ìjẹ́ anabi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni sisọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu awọn kọ̀kọ̀ ati ṣiṣẹlẹ rẹ bi o ṣe sọ.
  • Iyọnu si ibajẹ ko lẹtọọ tabi kikopa nibẹ, titako o si jẹ dandan.
  • Ti awọn adari ba da nnkan ti o tako Sharia silẹ, itẹle wọn nibi ìyẹn ko lẹtọọ.
  • Ailẹtọọ jijade si awọn adari Musulumi; nitori nnkan ti o wa ninu ìyẹn ninu ibajẹ ati ita ẹjẹ silẹ ati lílọ ifọkanbalẹ, itẹmọra ibajẹ awọn adari ẹlẹṣẹ, ati ṣíṣe suuru lori suta wọn rọrun ju ìyẹn lọ.
  • Irun, ọrọ rẹ tobi, oun ni iyatọ laaarin aigbagbọ ati Isilaamu.