Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba jade kuro ninu itẹle awọn adari, ti o tu ijọ Isilaamu ti o fẹnu ko lori ṣiṣe adehun fun olori, o wa ku lori isẹsi yẹn ninu ituka ati aitẹle, o maa ku ni iku awọn asiko aimọkan, awọn ti wọn ko ki n tẹle adari ti wọn ko ki n darapọ mọ ijọ kan, bi ko ṣe pe awọn ijọ ni wọn ati awọn ẹlẹyamẹya ti awọn kan maa n ba awọn kan ja ninu wọn. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe ẹni ti o ba ja lábẹ́ àsìá kan ti oju ododo ko han yatọ si ibajẹ nibẹ, ti o n binu nitori ẹlẹyamẹya lasan fun ìjọ rẹ tabi idile rẹ, ti ko ki n ṣe tori riran ẹsin ati ododo ṣe, ti o wa n ja ni ti ẹlẹyamẹya laini amọdaju ati imọ, ti wọn ba pa a lori isẹsi yẹn, o da gẹgẹ bii pipa ti asiko aimọkan ni. Ati pe dajudaju ẹni ti o ba jade si ijọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o pa ẹni rere rẹ ati ẹni buburu rẹ, ti ko bikita pẹlu nnkan ti o n ṣe ti ko si bẹru ijiya rẹ ninu pipa olugbagbọ rẹ, ti ko si pe adehun wọn fun awọn aladehun ninu awọn alaigbagbọ tabi awọn adari bi ko ṣe pe o n tu u ni, eleyii wa ninu ẹṣẹ ńláńlá, ati pe ẹni ti o ba ṣe e dajudaju o ti lẹtọọ si adehun iya ti o le koko yìí.