explain-icon

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n ṣe alaye wipe dajudaju ti awọn Musulumi ba kojọ lori olori kan, ati akojọpọ kan, lẹyin naa ni ẹni ti o fẹ ba a du ipo aṣẹ wa de, tabi ti o gbero lati pin awọn Musulumi si ijọ ti o pọ ju ẹyọkan lọ, o jẹ dandan fun wọn lati kọ fun un ati lati ba a ja; lati fi ti aburu rẹ danu ati lati fi da aabo bo ẹjẹ awọn Musulumi.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Jijẹ dandan gbigbọ ati titẹle alaṣẹ (oludari) awọn Musulumi nibi nkan ti kii ṣe ẹṣẹ, ati jijẹ eewọ jijade le e lori.
  • Ẹni ti o ba jade lori asiwaju awọn Musulumi ati akojọpọ wọn, dajudaju o jẹ dandan lati ba a ja bo ti le wu ki ipo rẹ o to ni ti iyi ati iran.
  • Ṣiṣenilojukokoro lori akojọpọ ati aisi ituka ati iyapa.