explain-icon

Àlàyé

Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju mo ti da gbogbo ẹṣẹ, ti mi ko fi ẹṣẹ kekere tabi ńlá kalẹ afi ki n ti ṣe e, njẹ wọn maa forí jin mi? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: Njẹ ṣe ko ki n ṣe pe o n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu ni, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni? O paara rẹ ni ẹẹmẹta, O da a lohun pe: Bẹẹni mo n jẹrii, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji fun un ati pipa awọn aburu rẹ̀ rẹ́, ati pe ironupiwada maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Titobi ijẹrii mejeeji ati titẹṣuwọn rẹ lori awọn ẹṣẹ fun ẹni ti o ba sọ ọ lododo lati inu ọkan rẹ.
  • Isilaamu maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.
  • Ironupiwada ododo maa n pa nnkan ti o ṣíwájú rẹ rẹ.
  • Pipaara nnkan ninu idanilẹkọọ wa ninu imọna Anabi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).
  • Ọla ti o n bẹ fun ijẹrii mejeeji, ati pe mejeeji jẹ okunfa fun igbala kuro nibi ṣíṣe gbere ninu ina.