explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti Mùsùlùmí meji ba pade ara wọn pẹ̀lú idà, ti ìkíni kejì wọn n gbero lati pa ìkejì rẹ; ẹni tí ó pa èèyàn maa wọ iná; tori pe oun ni o pa ikeji rẹ tààrà, Ọ̀rọ̀ ẹni tí wọ́n pa wa ru àwọn saabe lójú pe: Báwo ni o ṣe maa wọ ina? Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé torí pé oun naa fẹ́ pa ìkejì rẹ ni, ko si si nǹkan ti o kọ̀ fun un lati ma pa a ju pe ọwọ́ ẹni tí o pa a yá ju tiẹ̀ lọ ni.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ìní-ẹ̀tọ́ si ìyà ẹni ti o ba pinnu láti da ẹ̀ṣẹ̀ nínú ọkàn rẹ ti o si ṣe àwọn okùnfà rẹ tààrà.
  • Ikilọ ti o lágbára kúrò nibi ki awọn Mùsùlùmí maa ba ara wọn ja, ati àdéhùn ìyà iná lori ẹ.
  • Ìjà láàárín àwọn Musulumi pẹlu ẹ̀tọ́ kò kó sínú adehun ìyà naa, gẹgẹ bii bíbá àwọn ti o kọjá ẹnu-ala jà ati awọn obilẹjẹ.
  • Ẹni ti o ba da ẹṣẹ ńlá ko nii di Kèfèrí pẹlu ọ̀wọ́ pé ó kàn dá ẹṣẹ naa; torí pé Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe àwọn ti wọn n ba ara wọn jà ni Musulumi.
  • Ti Musulumi meji ba pade ara wọn pẹ̀lú èyíkéyìí nǹkan ti wọn le fi pa èèyàn, ti ọkan ninu wọn wa pa ikeji, ẹni ti o pa èèyàn ati ẹni tí wọ́n pa maa wọ ina, wọn kan dárúkọ idà ninu hadiisi naa lati fi ṣe àpèjúwe ni.