explain-icon

Àlàyé

Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun wa pe Musulumi ko nii jẹ ẹni tí igbagbọ rẹ pe titi ti yoo fi ti ìfẹ́ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣáájú ìfẹ́ ìyá rẹ, ati baba rẹ, ati ọmọkùnrin rẹ, ati ọmọbìnrin rẹ, ati awọn èèyàn ni apapọ, ìfẹ́ yii n beere fun itẹle e ati riran an lọ́wọ́, ati ki èèyàn ma yapa rẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Dandan ni níní ìfẹ́ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati titi i ṣáájú ìfẹ́ gbogbo ẹ̀dá.
  • Lara ami pípé ìfẹ́ ni: Ríran sunna ojiṣẹ Ọlọhun lọ́wọ́, ati níná ẹ̀mí ati dúkìá tori rẹ.
  • Ifẹ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n beere fun itẹle e nibi àṣẹ ti o ba pa, ati gbigba a ni olódodo nibi ohun ti o ba sọ, ati jíjìnnà si ohun ti o ba kọ̀, ati itẹle e, ati fifi adadaalẹ sílẹ̀.
  • Ẹ̀tọ́ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tobi o si kanpá ju ti gbogbo èèyàn lọ; torí pé o jẹ okùnfà imọna wa kúrò nibi anù, ati yíyọ wa kuro nibi iná, ati wiwọ alujanna.