Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pe dajudaju Mumini, daadaa ni gbogbo ẹ, ṣugbọn Mumuni ti o ni agbara ninu igbagbọ rẹ ati ipinnu rẹ ati dukia rẹ ati eyiti o yatọ si i ninu awọn ọna agbara ni oore ti Ọlọhun ti O biyi ti O gbọn-un-gbọn si tun nífẹ̀ẹ́ si i ju Mumini ti o jẹ ọlẹ lọ. Lẹyin naa ni o sọ asọtẹlẹ- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fun Mumini pẹlu ṣiṣe awọn igbiyanju nibi nkan ti yio ṣe e ni anfaani ninu awọn alamọri aye ati ọjọ ìkẹyìn, pẹlu fifara ti Ọlọhun ti O mọ ti ọla Rẹ si tun ga, ati wiwa iranlọwọ pẹlu Rẹ, ati gbigbe ara le E. Lẹyin naa o tun kọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kuro nibi ikagara ati ojuriro ati imaa ṣe ọlẹ nibi ṣiṣe nkan ti o maa ṣe anfaani ni aye ati ọrun. Ti Mumuni ba gbiyanju nibi iṣẹ, ti o si tun ṣe awọn okunfa, lẹni ti o n wa ikunlọwọ Ọlọhun, ti o si tun wa oore lati ọdọ Ọlọhun, ko wa sí nkankan fun un lẹyin rẹ ayaafi ki o fa gbogbo alamọri rẹ le Ọlọhun lọwọ, ki o si tun lọ mọ pe dajudaju èyí tí Ọlọhun ba sẹsa ni oore. Nitori naa ti adanwo ba ṣẹlẹ si i lẹyin ìyẹn, ko gbọdọ sọ pe: Ka ni mo ṣe bayii, nkan bayii bayii ni ko ba jẹ"; Ati pe dajudaju gbolohun (kani) maa n ṣina iṣẹ satani" nibi titako kadara, ati kika abamọ lori nkan ti o ti bọ, ṣugbọn o maa sọ lẹni ti o jupa jusẹ silẹ ti o si tun yọnu pe: "Kọddarọ Allāhu, wa maa Sha'a fa‘ala“, Ati pe nkan ti o ṣẹlẹ yẹn wa ni ibamu si nkan ti Ọlọhun gba lero, ati pe Aṣeyiowu-U ni In, ko si si ẹni ti o le da akọsilẹ rẹ pada, ati pe ko si ẹni ti o le dá idajọ rẹ pada.