explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti Ọlọhun ba fẹ oore fun ọkan ninu awọn ẹru Rẹ ti wọn jẹ mumini, o maa fi àdánwò kan wọn ninu ẹmi wọn ati dúkìá wọn ati ẹbi wọn, torí ìsádi Ọlọhun ti o maa ṣẹlẹ̀ si mumini ninu ẹ pẹ̀lú adua ati pipa awọn iṣẹ buruku rẹ́ ati agbega ní ipò.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Onigbagbọ òdodo maa ri oríṣiríṣi àdánwò.
  • Àdánwò le jẹ àmì ìfẹ́ Ọlọhun fun ẹrú Rẹ, titi ti yoo fi gbe ipò rẹ ga, ti o si maa pa àṣìṣe rẹ̀ rẹ́.
  • Ṣiṣenilojukokoro lori suuru nigba àdánwò, ki èèyàn má sì ba ara jẹ.