Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) gba musulumi níyànjú lati má kùú ayaafi ki o ni àbá daada si Ọlọhun pẹlu ki o fi abala inireti sọdọ Ọlọhun leke nígbàtí nba pọka iku lọwọ n'ireti pe Ọlọhun Yóò ṣekẹ rẹ yóò ṣe amojukuro fún un; nitoripe ifoya ni nkan ti wọn beere fún ki a le ri iṣẹ se daada, ìṣesí un kii se iṣesí iṣẹ ṣiṣe, nkan ti wọn fẹ nibẹ ni ki ireti borí.