Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe gbogbo iṣẹ́ pẹlu àníyàn ni, ìdájọ́ yii kárí gbogbo iṣẹ́ bii ìjọsìn ati ibalopọ. Ẹni ti o ba gbèrò anfaani kan pẹlu iṣẹ rẹ, anfaani yẹn naa ni o maa tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́, ko si si ẹsan kankan fun un, ẹni tí ó bá wa gbèrò isunmọ Ọlọhun pẹlu iṣẹ rẹ, o maa gba ẹsan kódà ki o jẹ iṣẹ lásán bii jijẹ ati mimu. Lẹ́yìn naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa fi àkàwé lélẹ̀ láti ṣàlàyé ilapa àníyàn nibi awọn iṣẹ pẹ̀lú didọgba wọn nibi àwòrán ti o hàn, o wa ṣàlàyé pe ẹni ti o ba gbèrò wíwá ìyọ́nú Ọlọhun pẹ̀lú hijra rẹ ati fifi ìlú rẹ sílẹ̀, hijra rẹ nǹkan ti o ba òfin mu ni ti a si maa tẹ́wọ́ gbà ti wọn si maa san an ni ẹsan lórí ẹ fun àníyàn òdodo rẹ, ẹni tí ó bá gbèrò anfaani ayé pẹ̀lú hijra rẹ, bii owó, tabi ipò, tabi òwò, tabi ìyàwó, anfaani yẹn ti o gbèrò naa ni o maa ri nibi hijra rẹ, ko si nii gba ẹsan.