Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- sọ fun wa wí pé ti musulumi ba ki Irun ni janmọọn, Irun rẹ ni ọla ju Irun rẹ ni ile tabi ni ọja lọ ni ọ̀nà igba ti o le ni ogún. Lẹ́yìn naa ni o sọ okùnfà ìyẹn: Oun naa ni pé ti ọkùnrin kan ba ṣe aluwala ti o si pari aluwala naa ti o si ṣe e daadaa, ti o wa jade lọ si mọ́sálásí, ti ko si si ohun ti o gbe e jade ayafi ìrun, ko nii gbe ẹsẹ kan àyàfi ki wọn ṣe ipo to ga ati aaye to ga fun un, ki wọn si tun fi pa àṣìṣe rẹ rẹ. Ti eniyan ba wọ inu mọṣalaṣi ti o si jokoo ti o n duro fun Irun, yìo gba ẹ̀san Irun lopin ìgbà tí ó bá ṣi n retí irun, àwọn Malaika a maa se adua fun un, ni igba ti o ba wa ni ori ìjókòó ti o ti kirun, wọn maa sọ pe: Ọlọhun, dárí jin in, Ọlọhun, ṣãnu fun un, Ọlọrun, gba ironupiwada rẹ,” , lopin ìgbà tí aluwala rẹ ko ba i tii bajẹ, ti ko si ṣe ipalara fun eniyan tabi awọn angẹli.