explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dandan ni ki eeyan ti aburu dànù kuro lọ́dọ̀ ara ẹni ati kúrò lọ́dọ̀ ẹlòmíràn, iru inira yòówù ko ri ki o jẹ, ko ni ẹtọ fun ẹnikẹ́ni ki o fi suta kan ara rẹ tabi ẹlòmíràn láìsí iyatọ. Ko si ni ẹtọ fun un ki o fi oró yaró; tori pe a kìí mu inira kúrò pẹ̀lú ìnira ayafi ti a ba fẹ gba ẹsan láìní kọjá ààlà. Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé àdéhùn ìyà ìpalára fun ẹni tí ba n ko ìpalára ba àwọn èèyàn, ati ìnira fun ẹni tí ba n ko ìnira ba àwọn èèyàn.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Idinamọ gbigba ẹsan pẹlu nǹkan ti o ju iru aburu ti wọn fi kan èèyàn lọ.
  • Ọlọhun ko pa ẹrú Rẹ ni àṣẹ pẹlu nǹkan ti o maa ko ìnira ba wọn.
  • Ṣíṣe ifi inira kan èèyàn ati gbigba ẹsan inira pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tabi ìṣe tabi gbigbe ju silẹ ni eewọ.
  • Ẹsan maa wa latara ìran iṣẹ, ẹni ti o ba ko ìpalára ba ẹlòmíì, Ọlọhun maa ko ìpalára ba a, ẹni tí ó bá fi ara ni ẹlòmíì, Ọlọhun maa fi ara ni oun naa.
  • Ọkan ninu awọn ofin Sharia ni pe: “A maa n mu ipalara kuro ni.” Sharia ko fi ọwọ́ si ipalara, o si kọ ipalara.