explain-icon

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ti nkankan ba n ru ninu iku ẹni ti n kirun, ti ko wa mọ boya nkan jade tabi nkankan o jade? Ko gbọdọ kuro ni ori irun, ko si gbọdọ ja a lati lọ tun aluwala ṣe, titi ti yio fi ri bibẹ ẹgbin ni aridaju eleyii ti o le ba aluwala jẹ; pẹlu pe ki o gbọ didun iso, tabi ki o gbọ oorun; tori pe dajudaju nkan ti a ti mọ amọdaju rẹ ko lee yẹ pẹlu iyemeji, ati pe oun ti mọ amọdaju imọra, ti ẹgbin si jẹ nkan ti n ṣe iyemeji ninu rẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Hadīth yii ipilẹ kan ni ninu awọn ipilẹ Isilaamu, o tun jẹ òfin kan ninu awọn ofin agbọye ẹsin, oun ni pe: Dajudaju amọdaju ko lee yẹ pẹlu iyemeji, ati pe ipilẹ ni wiwa nkan ti o n bẹ lori ohun ti o n bẹ lori rẹ, titi ti nkan ti o yatọ si iyẹn fi maa daju.
  • Iyemeji o ki n lapa nibi imọra, ati pe ẹni ti n kirun si wa lori imọra rẹ lopin igba ti ko ba tii ni amọdaju ẹgbin.