Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ran àwọn saabe rẹ pe ki wọn ma fi ère- oun ni aworan nǹkan ti o ni ẹmi ti o jẹ abara tabi eyi ti ko ni ara- kan kan sílẹ̀ afi ki wọn mu u kuro tabi ki wọn pa a rẹ. Ki wọn si ma fi sàréè ti o ga kan kan sílẹ̀ ayafi ki wọn jẹ ki o ba ilẹ̀ dọ́gba, ki wọn si wó nǹkan ti wọn kọ́ sori ẹ, tabi ki wọn ṣe e ni nǹkan ti o maa tẹ́ pẹrẹsẹ ti ko nii ga nílẹ̀ pupọ, ṣùgbọ́n o maa ga ni odiwọn àlààfo ti o wa laarin ìka àtàǹpàkò ati ika ọmọndinrin.