Nínú ìtọ́sọ́nà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni pe o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, o si maa gbe wọn sókè- gẹgẹ bi ẹni tí n ṣe adua- o maa wa rọra fẹnu fẹ́ atẹ́gùn si i pẹ̀lú itọ́ díẹ̀, o maa ka àwọn suura mẹtẹẹta naa: {Qul Uwal Loohu Ahad} ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq} ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹ́yìn náà ni o maa fi atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pa ibi ti o ba ṣee pa ni ara rẹ; o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ, ati ojú rẹ, ati ẹya iwaju ara rẹ, o maa pààrà rẹ ni ẹẹmẹta.