Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n tọka yin si nnkan ti Ọlọhun fi maa n pa awọn àṣìṣe rẹ, ti O si fi maa n gbe awọn ipo ga?" Wọn sọ pe bẹẹni irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: "Ṣíṣe aluwala ni pípé lori ìnira, ati gbigbe igbẹsẹ pupọ lọ si mọsalasi, ati rireti irun lẹyin irun, ìyẹn ni ida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú". O ni alaafia - Muslim gba a wa
explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi awọn saabe rẹ leere pe ṣe wọn fẹ ki oun tọka wọn si awọn iṣẹ ti o maa jẹ okunfa aforijin awọn ẹṣẹ, ati iparẹ rẹ kuro ninu awọn iwe awọn mọlaika ti wọn n kọ iṣẹ, ati gíga awọn ipò ninu alujanna? Awọn saabe sọ pe: Bẹẹni a fẹ ìyẹn. O sọ pe: Akọkọ: Kikari ati pipe aluwala lori inira; gẹgẹ bii otutu, ati kíkéré omi, ati inira ara, ati omi gbigbona. Ikeji: Ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbesẹ- oun ni nnkan ti o wa laaarin ẹsẹ mejeeji- lọ si awọn mọsalasi latara jijina ilé, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ pipaara. Ikẹta: Rireti asiko irun, ati sisopọ ọkan mọ ọn, ati ìgbáradì fun un, ati jijokoo sinu mọsalasi fun ireti janmọọn, ti o ba ti ki i ki o maa reti irun miiran ni aaye ti o ti kirun. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju awọn àlámọ̀rí yii gan-an ni dida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú; nitori pe o maa n kọdi awọn oju ọna èṣù lọ sọ́dọ̀ ẹmi, o si maa n bori ifẹ inu, ti o maa kọ fun un kuro nibi gbigba awọn royiroyi wọle, ti ijọ Ọlọhun fi maa bori awọn ọmọ ogun èṣù pẹlu rẹ; ìyẹn ni ijagun soju ọna Ọlọhun ti o tobi julọ, o waa wa ni ipo dida ààbò bo ẹnu ààlà ìlú ọ̀tá.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Pataki sisọ irun janmọọn ninu mọsalasi ati ifiye si awọn irun àti ṣíṣàì jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà kúrò nibẹ.
  • Didaa agbekalẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati mimu awọn saabe rẹ jẹ̀rán nigba ti o bẹ̀rẹ̀ fun wọn pẹlu ẹsan ti o tobi ni ọna ibeere, ati pe ọna yii wa ninu awọn ọna ikọnilẹkọọ.
  • Anfaani ti o n bẹ nibi ṣíṣe àfihàn ọ̀rọ̀ pẹlu ìbéèrè ati idahun ni: Ki ọrọ le wọni lọ́kàn gan-an nítorí kiko àìṣekedere pọ̀ mọ́ ìṣekedere.
  • An-nawawi- ki Ọlọhun kẹ ẹ- sọ pe: FAZAALIKUMU-R-RIBAAT n túmọ̀ si: Ribaat ti a fẹ́, ipilẹ ribaat si ni ki èèyàn di nǹkan mú ṣinṣin, bii ìgbà tí o de ẹ̀mí ara rẹ mọ́lẹ̀ fun itẹle aṣẹ yii, wọn sọ pé: Òun ni o daa julọ ninu awọn ribaat gẹgẹ bi wọn ṣe sọ pe: Ijagun soju ọna Ọlọhun ni jija ẹ̀mí lógun, o si tun le túmọ̀ si ribaat ti o rọrun, o n túmọ̀ si pe: O wa ninu awọn oríṣiríṣi ribaat.
  • Wọn paara gbolohun "Ar-Ribaat" wọn si so Alif ati Laam mọ́ ọn; ìyẹn jẹ igbetobi fun àlámọ̀rí awọn iṣẹ yìí.