Abdullahi ọmọ Zaid- ki Ọlọhun yọnu si i- ṣàlàyé bi aluwala Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ri, pẹlu aworan ti iṣẹ, Ni o ba beere fun igba kekere kan ti omi wa ninu ẹ, O kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹlu fifọ ọwọ rẹ mejeeji, lẹyin naa o tẹ igba naa o si da omi, o si fọ mejeeji lẹẹmẹta si ita igba naa, Lẹyin naa o ti ọwọ rẹ bọ inu igba, o si bu omi gẹẹ mẹta, ti o n yọ ẹnu ninu gbogbo gẹẹ kọọkan ti o si n fin omi si imu ti o si n fin in sita pada, Lẹyin naa o bu omi ninu rẹ ti o si fọ oju rẹ lẹẹmẹta, Lẹyin naa o bu omi ninu rẹ ti o si fọ ọwọ rẹ mejeeji titi de igunpa mejeeji ni ẹẹmeji ẹẹmeji, Lẹyin naa, o ti ọwọ rẹ mejeeji bọ inu igba ti o si pa ori rẹ pẹlu ọwọ rẹ lati ibi ti irun rẹ ti bẹ̀rẹ̀ titi ti o fi de ipakọ rẹ ni oke ọrun, lẹyin naa, o da mejeeji pada titi o fi de aaye ti o ti bẹ̀rẹ̀ nibẹ, Lẹyin naa, o fọ ẹsẹ rẹ mejeeji pẹlu kokosẹ mejeeji.