Lati ọdọ Abdullah ọmọ Amru ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji o sọ pe: A ṣẹri pada pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - lati Makkah lọ si Madina titi ti a fi kan omi ni oju-ọna, awọn ikọ kan yara fun irun Asri, ti wọn si ṣe aluwala ni ẹni ti n kanju, ni a ba wa ba wọn ti awọn gigisẹ wọn han ti omi o si de ibẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: «Egbe ki o maa ba gbogbo gigisẹ (ti omi o de) ninu ina, ẹ ṣe aluwala yin daadaa». O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣe irin-ajo lati Makkah lọ si Madina ti awọn saabe rẹ si wa pẹlu rẹ, ni oju-ọna wọn wọ́n rí omi, ti apakan ninu awọn saabe sì yara ṣe aluwala fún irun Asri debi pe gbigbẹ awọn gigisẹ fun omi han si kedere, ni Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- wa sọ pe: Iya ati iparun ninu ina n bẹ fun gbogbo olùṣe aseeto nibi fifọ gigisẹ nibi aluwala, o si tun pa wọn lasẹ ki wọn maa ṣe aluwala ni pipe.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Jijẹ dandan fifọ ẹsẹ mejeeji nibi aluwala; torí pé dajudaju ti pipa a ba lẹtọọ ni ko nii ṣe adehun ina fun ẹni ti o fi fifọ gigisẹ silẹ.
  • Jijẹ dandan fifi omi kari gbogbo awọn oríkèé ara ti a maa n fọ, ati pe ẹnikẹni ti o ba fi aaye kekere kan silẹ ninu nkan ti fifọ rẹ jẹ dandan ni ti imọọmọ ṣe ati ailakasi, irun rẹ ko ni alaafia.
  • Pataki kikọ alaimọkan ni ẹkọ ati ṣiṣe amọna rẹ.
  • Onimimọ a maa kọ nkan ti o ba ri nibi rira ọranyan ati sunnah lare pẹlu ọna ti o ba wa ni ibamu.
  • Muhammad Ishāq Ad-dahlawiy sọ pe: Iran mẹta ni Isbāg: *Ọranyan* oun naa ni mimu omi kari gbogbo aaye naa (oríkèé ara ti a fẹ fọ) ni ẹẹkan, ati *Sunnah* oun naa ni fifọ ni ẹẹmẹta, ati *Eyiti a fẹ* oun naa ni fifa a gun pẹ̀lú fifọ ni ẹẹmẹta.