explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba mii ti o ba fẹ ṣe aluwala, o maa n fọ gbogbo orikee ninu awọn orikee aluwala lẹẹmeji, o maa fọ oju- ti gbigbo ẹnu ati fifa omi simu n bẹ nibẹ- ati ọwọ mejeeji ati ẹsẹ mejeeji lẹẹmeji.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Eyi ti o jẹ dandan ni fifọ awọn orikee lẹẹkan ati pe eyi ti o ba lekun jẹ nnkan ti a fẹ.
  • Ṣíṣe lofin ṣíṣe aluwala lẹẹmeji meji nigba mii.
  • Nnkan ti a ṣe lofin nibi pipa ori ni ẹẹkan.