Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé àwọn nǹkan ti ṣíṣe wọn wa ninu ẹbọ, ninu wọn ni: Akọkọ: Ọfọ̀: Oun ni ọ̀rọ̀ ti àwọn ara àsìkò ki Isilaamu to de fi maa n ṣe ìwòsàn, ti o ni ẹbọ nínú. Ìkejì: Àsokọ́ra lati ara ìlẹ̀kẹ̀ ati nǹkan ti o jọ ọ: Eyi ti wọn maa n so kọ ọmọdé lọrun, ati awọn ẹran-ọ̀sìn, ati nǹkan ti o yatọ si i, lati ti ojukoju dànù. Ikẹta: Oogun ifẹran: Eyi ti wọn ṣe lati jẹ ki ọkọ ati ìyàwó nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àwọn nǹkan wọ̀nyí wa nínú ẹbọ; torí pé o wa ninu fifi nǹkan ṣe okùnfà, ti kii sii ṣe okùnfà ti o ba òfin mu ti o rinlẹ pẹ̀lú ẹ̀rí, kii sii ṣe okùnfà ti ìmọ̀lára ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí. Ṣùgbọ́n àwọn òkùnfà ti o ba ofin mu gẹ́gẹ́ bii kika Kuraani, tabi eyi ti o jẹ ti ìmọ̀lára gẹ́gẹ́ bii àwọn oògùn ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí, èyí ni ẹtọ pẹlu adisọkan pe okùnfà ni, ati pe àǹfààní ati ìnira wa lọ́wọ́ Ọlọhun.