Arakunrin kan ninu awọn ara oko wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati tọ ọ sọ́nà lori iṣẹ ti o maa mu u wọ alujanna, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe dajudaju wiwọ alujanna ati lila kuro nibi ina, méjèèjì duro lori pipe awọn origun Isilaamu, bii ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo, ati ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn. Ki o maa gbe irun maraarun-un ti Ọlọhun ṣe wọn ni dandan lori awọn ẹru Rẹ duro ni gbogbo ọsan ati oru. Ki o maa yọ saka owo ti Ọlọhun ṣe ni dandan lori rẹ, ki o si fun ẹni ti o lẹtọọ si i. Ki o maa ṣọ awẹ Ramadan ni asiko rẹ. Arakunrin naa sọ pe mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura pe mi ko nii lekun nnkan kan lori iṣẹ ti a ṣe ni ọran-anyan ti mo gbọ́ lọdọ rẹ ninu awọn itẹle, mi ko si nii dinkun ninu rẹ. Nigba ti o pẹyin da, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹni ti o ba dun mọ ọn ninu lati wo arakunrin kan ninu awọn ara alujanna, ki o yaa wo larubawa oko yii.