Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun awọn saabe nípa ìṣẹ́gun awọn mùsùlùmí lori awọn Juu Khaibar ni ọjọ keji, ìyẹn maa waye lati ọwọ arakunrin kan ti oun maa fun un ni asia, oun naa ni àsíá tí àwọn ọmọ ogun maa n fi ṣe àmì wọn, Ati pe arakunrin yii ninu awọn iroyin rẹ ni pe o nífẹ̀ẹ́ Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ, ti Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ naa si nífẹ̀ẹ́ rẹ, Àwọn saabe si sùn ni alẹ ti wọn n jíròrò ti wọn si n sọ̀rọ̀ nipa pe tani wọn maa fun ni asia naa? Ni ti ìfẹ́ si iyì ńlá yii, Nigba ti o di àárọ̀ wọn lọ sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, gbogbo wọn ni wọ́n n nírètí pé àwọn á gba iyì yìí, Ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa beere nipa 'Ali ọmọ Abu Talib- ki Ọlọhun yọnu si i-? Wọn sọ pé: O rẹ ẹ, ojú rẹ mejeeji n dun un. Ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ranṣẹ si i, wọn si de pẹlu rẹ, o wa tu itọ si oju 'Ali mejeeji ninu itọ rẹ abiyi, o ṣe adura fun un, o si gbádùn nibi aisan rẹ, o wa da gẹgẹ bii pe inira kan ko mu u tẹ́lẹ̀, o wa fun un ni asia naa, o pa a láṣẹ pẹlu pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ titi o fi maa sunmọ aaye ààbò awọn ọta ti o si maa fi gbigba Isilaamu lọ wọn, ti wọn ba da a lohun; o maa sọ fun wọn nnkan ti o jẹ dandan fun wọn ninu awọn ọran-anyan. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé fun 'Ali nipa ọla ti o n bẹ fun ipepe lọ si oju ọna Ọlọhun ati pe ti ipepe ba jẹ okunfa ìtọ́sọ́nà arakunrin kan ṣoṣo ìyẹn loore fun un ju ki rakunmi pupa jẹ tirẹ̀ lọ, eyi ti o ṣe pe oun ni o níye lórí julọ ninu awọn dukia larubawa, yio ni i tabi ki o fi ta ọrẹ.