Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe atọ ireke- oun ni omi funfun ti kò ki ti o maa n fà tìkọ̀, o maa n jade lati inu nnkan ọmọkunrin nigba adun tabi ṣíwájú ibalopọ- maa n jáde lara oun lọpọlọpọ, Ko si mọ bi o ṣe maa ṣe pẹlu jijade rẹ, o wa tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-; nitori pe o jẹ ọkọ Fatimah ọmọbìnrin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa tọrọ lọdọ Miqdad ọmọ Al-Aswad lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa ìyẹn, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe: Ki o fọ nnkan ọmọkunrin rẹ lẹyin naa ki o ṣe aluwala.