Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- kọ fun ẹni ti o ba fẹ gbọ bukaata itọ tabi igbẹ ki o da oju kọ kibula ati agbegbe kaaba, ki o si ma tun da ẹyin kọ ọ; amọ o jẹ dandan fun un ki o yi si ila oorun tabi iwọ oorun ti kibula rẹ ba jọ kibula awọn ara Madinah. Lẹyin naa ni Abu Ayyūb wa funni ni iro pe nígbà tí wọn de Shām wọn ri awọn ile igbọnsẹ nibẹ ti wọn ti pese kalẹ fun gbigbọ bukaata ti wọn da oju wọn kọ kaaba, nitori naa wọn maa n yi ara wọn kuro ni kibula, ti wọn si tun maa n toro aforijin Ọlọhun pẹlu bẹ́ẹ̀.