Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye wipe dajudaju iṣẹ oloore ṣiṣe ninu ọjọ mẹwaa akọkọ ninu oṣu Dhul Hijjah lọla ju awọn ọjọ ọdun yooku lọ. Ni awọn saabe - ki Ọlọhun yọnu si wọn - wa beere lọwọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nipa jijagun si oju ọna Ọlọhun ninu ọjọ ti o yatọ sí àwọn ọjọ mẹwaa yii wipe ṣe oun ni o ni ọlá julọ ni àbí awọn iṣẹ oloore ninu awọn ọjọ yii? Latari ohun ti o rinlẹ lọdọ wọn wipe jijagun si oju ọna Ọlọhun wa nínú àwọn iṣẹ ti o lọla julọ. Nigba naa ni o wa fesi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe: Dajudaju iṣẹ oloore ṣiṣe ninu awọn ọjọ yii lọla ju jijagun si oju ọna Ọlọhun ninu ọjọ ti o yatọ si i lọ, ayaafi arakunrin kan ti o jade ni ẹni ti n jagun ti o si n fi ẹmi rẹ ati dukia rẹ wewu ni oju ọna Ọlọhun, ti o wa padanu dukia rẹ ti ẹmi rẹ naa si tun bọ sí oju ọna Ọlọhun, Irufẹ iṣẹ yii ni yio lọla ju iṣẹ oloore ninu awọn ọjọ ọlọla yii lọ.