explain-icon

Àlàyé

Òjíṣẹ Ọlọhun (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa ní ìró idunnu pé ẹni tí eruku bá bo ẹsẹ rẹ mejeeji nígbàtí o njagun sí oju-ọna Ọlọhun pe iná kò ní jó ẹni na.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • ìfunni ní ìró idunnu fún olujagun sí ojú ọna Ọlọhun pe yóò rí ìgbàlà ati àkóyọ níbi Iná.
  • Anọbi darukọ gigisẹ mejeeji bó ti ẹ jẹ pé erukuru náà yóò kárí gbogbo ara lapapọ; nitoripé ọpọlọpọ awọn olujagun nigbà náà ni wọn nfi ẹsẹ rìn, ti gigiṣẹ wọn yóò sì kó eruku ni gbogbo iṣesí.
  • Ibn Hajar ṣọ pe: ti o bá ṣe pé kí eruku kan gigisẹ lasan ni yóò ṣe iná leewọ fún ni, bá wo wa ni ti ẹni ti o bá ṣe akitiyan ti o tun lo igbiyanju rẹ, ti o si lo gbogbo oun tó ní nikapa.