Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye pé ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun Ọba Aleke ọla, tí kò sì bá obinrin lopọ, itumọ ibalopọ ni ibasun ati awọn ohun ti o ṣiwaju rẹ̀ gẹgẹ bii ifẹnukonu ati ifarakanra, wọn si maa n túmọ̀ rẹ̀ si ọrọ buruku, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, nípa dídá ẹ̀ṣẹ̀ àti ṣíṣe aburú. Ninu rírú ofin Ọlọhun ni ṣiṣe awọn èèwọ̀ gbígbé harami, yoo pada sile lati Hajji rẹ̀ ní ẹniti Ọlọhun ti darijin, gẹgẹ bi wọn ti n bi ọmọde lai ni ẹṣẹ kankan lọrun.