explain-icon

Àlàyé

Awọn saabe - ki Ọlọhun yọnu si wọn - maa n ri ijagun si oju-ọna Ọlọhun ati biba awọn ọta ja ni iṣẹ ti o fi n lọla julọ, Ni Āisha - ki Ọlọhun yọnu si i - wa bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ṣe awọn naa o nii jagun ni? Ni o wa juwe wọn - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lọ sí ibi jihad ti o lọla julọ fun wọn, oun naa ni hajj atẹwọgba (ti o mọ kanga) eleyii ti o ṣe deedee tira Ọlọhun ati sunnah Anabi, ti o si tun la kuro nibi ẹṣẹ ati ṣekarimi.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Jijagun sí oju-ọna Ọlọhun ninu awọn iṣẹ ti o lọla julọ fún awọn ọkunrin lo wa.
  • Hajj lọla fun awọn obinrin ju jijagun lọ, ati pe o wa ninu awọn iṣẹ ti o lọla julọ fun wọn.
  • Awọn iṣẹ maa n ni ọla ju ara wọn lọ ni ibamu si oṣiṣẹ.
  • O pe hajj ni jihad; nítorí pé ijagun ẹmi ni, o sì tun ko inawo sinu, ati agbara ti ara, nitori naa o jẹ ijọsin ara ati owo gẹgẹ bii jijagun sí oju-ọna Ọlọhun.