explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iṣesi ṣọbẹ-ṣelu pe o da gẹgẹ bii aguntan ti o n ṣe iyemeji ti ko mọ eyi ti o maa tẹle ninu agbo aguntan méjèèjì, O maa lọ ba agbo yii nigba mii, a tun lọ ba omiran nigba mii, Wọn wa ninu idaamu-daabo laaarin igbagbọ ati aigbagbọ, wọn ko si pẹlu awọn olugbagbọ ni ti gbangba ati ni kọkọ, wọn ko si tun si pẹlu awọn alaigbagbọ ni gbangba ati ni kọkọ, bi ko ṣe pe gbangba wọn wa pẹlu awọn olugbagbọ, ti kọkọ wọn si wa nibi iyemeji ati aisi lojukan, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ninu itọsọna Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni fifi àpẹrẹ lelẹ lati mu awọn ìtumọ̀ sunmọ.
  • Alaye iṣesi awọn ṣọbẹ-ṣelu bii aisi lojukan ati iyemeji ati aiduroṣinṣin.
  • Ikilọ nipa iṣesi awọn ṣọbẹ-ṣelu ati ṣiṣeni lojukokoro lori ododo ati ipinnu nibi igbagbọ ni gbangba ati ni kọkọ.