Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun awọn saabe rẹ nipa dajjal ati awọn iroyin rẹ ati awọn ami rẹ pẹlu nǹkan ti Anabi kan ko sọ ri ṣíwájú rẹ, ninu ìyẹn ni: Pe o jẹ olójú kan. Ati pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fi nnkan ti o daa bii alujanna ati ina pẹlu rẹ, ni ibamu si riri oju. Ṣugbọn alujanna rẹ jẹ iná, ti ina rẹ si jẹ alujanna, ẹni ti o ba tẹle e o maa mu u wọ inu alujanna yii ninu nnkan ti awọn eniyan n ri, ṣùgbọ́n ina ti o n jóni ni, ẹni ti o ba yapa rẹ o maa mu u wọ ina ninu nnkan ti awọn eniyan n ri, ṣùgbọ́n alujanna ti o daa ni, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ fun wa kuro nibi wahala rẹ gẹgẹ bi Nuh ṣe ṣekilọ fun ijọ rẹ pẹlu rẹ.