explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ nipa awọn ti wọn buru julọ ninu awọn eniyan, awọn ni ẹni ti ọjọ igbedide to le wọn lori ti wọn si wa ni alààyè, ati awọn ti wọn maa n mu awọn saare ni awọn mọsalasi, ti wọn maa n kirun nibẹ ati si wọn lara.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ṣíṣe mimọ awọn mọsalasi lori awọn saare leewọ; nitori pe oju ọna lọ sibi ẹbọ ni.
  • Ṣíṣe kiki irun nibi saare leewọ, koda ki wọn ma mọ ọn; nitori pe mọsalasi jẹ orúkọ fun ibi ti wọn ba maa n forikanlẹ nibẹ, koda ki nǹkan ti wọn ba mọ ma wa lori rẹ.
  • Eni ti o ba mu awọn saare awọn ẹni rere ni awọn mọsalasi fun irun kiki nibẹ, o wa ninu awọn ti wọn buru julọ ninu awọn eniyan, koda ki o ro pe erongba rẹ ni wiwa asunmọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.