Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ẹsin yìí maa pada kari gbogbo àwọn ipin ilẹ̀, èyíkéyìí aaye ti oru ati ọsan de ni ẹsin yìí maa pada de, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko nii fi ile kan sílẹ̀ láéláé ni awọn ilu ati awọn oko tabi ni aṣalẹ afi ki O mu ẹsin yii wọnu rẹ, Ẹni ti o ba gba ẹsin yii ti o si ni igbagbọ ninu rẹ dajudaju o maa di abiyi pẹlu iyi Isilaamu, Ẹni ti o ba kọ ọ ti o saigbagbọ pẹlu rẹ o maa di ẹni yẹpẹrẹ ati eni ẹtẹ. Lẹyin naa, saabe ti o n jẹ Tamiim Ad-Daari- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe oun mọ ìyẹn ti ojiṣẹ Ọlọhun sọ lara awọn ara ile rẹ, torí pé ẹni ti o gba Isilaamu ninu wọn ri oore ati iyi, ẹni ti o ṣe aigbagbọ ninu wọn si ri iyẹpẹrẹ ati ẹtẹ pẹlu owo ti o tun n san fun awọn Mùsùlùmí.