Uthman ọmọ ‘Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- fẹ tun mọsalasi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ni irisi ti o daa ju kikọ akọkọ rẹ lọ, ni awọn eniyan ba korira ìyẹn; fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu yiyi kikọ mọsalasi naa pada kuro nibi isẹsi kikọ rẹ ni aye Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mọsalasi jẹ nnkan ti wọn mọ pẹlu amọ̀, ati pe òrùlé rẹ wọn mọ ọn latara imọ̀ ọ̀pẹ, ṣugbọn Uthman fẹ kọ ọ pẹlu awọn okuta ati ẹfun, Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fun wọn nipa rẹ, ati pe oun gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan lati fi wa iyọnu Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga- ti ko kii ṣe ni ti karimi tabi kagbọmi, Ọlọhun A san-an lẹsan ni eyi ti o daa julọ ninu ẹsan ninu iran iṣẹ rẹ, ati pe ẹsan yii oun ni ki Ọlọhun kọ iru rẹ fun un ninu alujanna.