explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ki a ma maa bú àwọn òkú, ati pe eyi wa ninu awọn iwa buruku; torí pé wọn ti de ibi ti nǹkan ti wọn ti síwájú wa ninu iṣẹ rere tabi buruku, gẹgẹ bi o ṣe jẹ́ pé èébú yii ko lee dé ọdọ wọn, o kan maa kó sùtá ba àwọn alààyè ni.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Hadiisi naa n tọka si ṣíṣe bíbú àwọn òkú ní eewọ.
  • O n bẹ nibi gbígbé bibu àwọn òkú jù silẹ ṣiṣọ anfaani àwọn alààyè, ati mímú ojú to ààbò àwùjọ kuro nibi ọta ati ìkórìíra.
  • Ọgbọ́n ti n bẹ nibi kikọ bibu wọn ni pe wọn ti de ibi ti nǹkan ti wọn ti síwájú wa; torí naa eebu wọn ko ṣe anfaani, ati pe sùtá wa nibẹ fun awọn mọ̀lẹ́bí rẹ ti wọn wa láàyè.
  • Kò lẹtọọ fun ọmọniyan lati maa sọ nǹkan ti ko ba si anfaani ninu ẹ.