Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, sọ pe oun yoo ni abàtà kan ni Ọjọ Ajinde, ti òró rẹ yoo jẹ irin oṣu kan, ti ìbú rẹ naa si maa jẹ irin oṣù kan, Omi rẹ funfun ju wara lọ, Oorun rẹ dun ju ti alumisiki lọ, Àwọn àgé omi rẹ̀ pọ̀ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi àgé omi náà mu omi ninu abata naa, òùngbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láéláé.