Awọn ijọ kan wa ba Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, nigba ti wọn de ọdọ rẹ wọn sọ - ni ẹni ti n yin in - awọn ọrọ eleyii ti o korira rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, Ni wọn wa sọ pe: "Iwọ ni olowo wa", Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun wọn pe: Allāhu ni Olowo. Nitori naa o n bẹ fun Un iyi (isiwaju) ti o pe lori awọn ẹru Rẹ, ati pe awọn ni ẹrusin Rẹ. Ni wọn wa sọ pe: Iwọ ni "ẹni ti o lọla julọ ninu wa" ti o si tun ga jùlọ ni ipo ati iyi ati ẹyẹ. Ati pe iwọ ni "ẹni ti o tobi julọ ninu wa ni ọrọ" ti o tun pọ julọ ni ọrẹ tita ati giga. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa tọ́ wọn sọna pe ki wọn máa sọ gbolohun wọn ti wọn ti ba saaba ki wọn o si ma la awọn gbolohun kan bọ ara wọn lọrun, ki esu ma lọ ti wọn lọ si ibi aseju ati ayinju eleyii ti maa n muni ko sinu nkan ti wọn ṣe leewọ ni ẹbọ (imu orogun mọ Ọlọhun) ati awọn atẹgun rẹ.