Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fi apẹrẹ le'lẹ fun awọn ti wọn duro nibi aala Ọlọhun, awọn ti wọn duro deede lori aṣẹ Ọlọhun, awọn ti wọn n pàṣẹ daadaa, awọn ti wọn n kọ ibajẹ, Ati pe apejuwe awọn ti wọn ko sinu awọn aala Ọlọhun ti wọn n fi daadaa silẹ, ti wọn n wu iwa ibajẹ, ati oripa iyẹn nibi lila awujọ, da bi apejuwe ijọ kan ti wọn gun ọkọ oju-omi, ni wọn wa mu aje lati mọ awọn ti wọn maa jokoo si oke ọkọ oju-omi ati awọn ti wọn maa jokoo si isalẹ rẹ, ni awọn kan wa wa ni oke rẹ, ti awọn kan si wa ni isalẹ rẹ, ti awọn ti wọn wa ni isalẹ ba wa fẹ pọn omi wọn a lọ si ọdọ awọn ti wọn wa ni oke wọn, Ni awọn ti wọn wa ni isalẹ wa sọ pe: Ti awa ba le lu oju kan ni aaye wa ni isalẹ ti a maa ti ibẹ mumi, ki a ma baa maa ni awọn ti wọn wa ni oke wa lara, ti awọn to wa l'oke ba fi wọn silẹ lati ṣe nkan yẹn, ọkọ oju-omi yẹn a tẹ gbogbo wọn ri, ṣugbọn ti wọn ba dide lati kọ fun wọn nibi iyẹn, awọn ijọ mejeeji ni yio la papọ.