explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju riranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu awọn gbolohun ti wọn tobi yii loore ju aye ati nnkan ti o wa ninu rẹ lọ, awọn naa ni: “Subhaanallah”: Afọmọ ni fun Ọlọhun kuro nibi awọn adinku. “Alhamdulillah”: Ẹyin ni fun Un pẹlu awọn iroyin pipe pẹlu nini ifẹ Rẹ ati gbigbe E tobi. “Laa ilaaha illallohu”: ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Ọlọhun. “Allahu Akbar”: Ẹni ti O tobi julọ ti O gbọnngbọn ju gbogbo nnkan lọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ṣisẹnilojukokoro lori iranti Ọlọhun, ati pe o jẹ nnkan ti a nifẹẹ ju nnkan ti oorun ran le lori lọ.
  • Ṣisẹnilojukokoro lori mimaa ṣe iranti lọpọlọpọ; nitori nnkan ti o wa nibẹ bi ẹsan ati ọla.
  • Igbadun aye kere ati pe awọn adun rẹ maa tan.