explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé iranti Ọlọhun tó lọ́lá jùlọ ni: "LAA ILAAHA ILLALLOOH" itumọ rẹ̀ ni pé kò sí nkankan tí a gbọdọ̀ jọsin fun pẹlu ododo ayafi Ọlọhun Allah, ati pé adura tó lọ́lá jùlọ ni ALHAMDULILLAH; iyẹn ni pé a n fi rinlẹ̀ pé dajudaju Allahu ni Oluṣedẹra fún wa, Oun ni O sì lẹtọọ si iroyin tó pé, tó sì dara julọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ìgbani ní ìyànjú lati maa ṣe iranti Ọlọhun ni pupọ pẹlu gbolohun iṣe Ọlọhun lọ́kan, ati lati maa gbadura pẹlu gbolohun ọpẹ́.